Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 8:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Solomoni papejọ awọn agba Israeli, ati gbogbo awọn olori awọn ẹ̀ya, awọn olori awọn baba awọn ọmọ Israeli, si ọdọ Solomoni ọba ni Jerusalemu, ki nwọn ki o lè gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá lati ilu Dafidi, ti iṣe Sioni.

2. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pe ara wọn jọ si ọdọ Solomoni ọba ni ajọ ọdun ni oṣu Etanimu, ti iṣe oṣu keje.

3. Gbogbo awọn agbàgba Israeli si wá, awọn alufa si gbe apoti-ẹri.

4. Nwọn si gbe apoti-ẹ̀ri Oluwa wá soke, ati agọ ajọ enia, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ ani nkan wọnni ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi gbe goke wá.

5. Ati Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀ niwaju apoti-ẹri, nwọn nfi agutan ati malu ti a kò le mọ̀ iye, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ rubọ.

6. Awọn alufa si gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀ sinu ibi-idahùn ile na, ni ibi mimọ́-julọ labẹ iyẹ awọn kerubu.

7. Nitori awọn kerubu nà iyẹ wọn mejeji si ibi apoti-ẹri, awọn kerubu na si bò apọti-ẹri ati awọn ọpá rẹ̀ lati oke wá.

8. Nwọn si fa awọn ọpá na jade tobẹ̃ ti a nfi ri ori awọn ọpá na lati ibi mimọ́ niwaju ibi-idahùn, a kò si ri wọn lode: nibẹ ni awọn si wà titi di oni yi.