Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 12:18-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Nigbana ni Rehoboamu ọba, ran Adoramu ẹniti iṣe olori iṣẹ-iru; gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Nitorina Rehoboamu, ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀, lati sá lọ si Jerusalemu.

19. Bẹ̃ni Israeli ṣọtẹ̀ si ile Dafidi titi di oni yi.

20. O si ṣe nigbati gbogbo Israeli gbọ́ pe Jeroboamu tun pada bọ̀, ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pè e wá si ajọ, nwọn si fi i jọba lori gbogbo Israeli: kò si ẹnikan ti o tọ̀ ile Dafidi lẹhin, bikoṣe kiki ẹya Juda.

21. Nigbati Rehoboamu si wá si Jerusalemu, o ko gbogbo ile Juda jọ, pẹlu ẹya Benjamini, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba ile Israeli ja, lati mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.

22. Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Ṣemaiah, enia Ọlọrun wá wipe,

23. Sọ fun Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo ile Juda ati Benjamini, ati fun iyokù awọn enia wipe,

24. Bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò gbọdọ goke bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ẹ pada olukuluku si ile rẹ̀; nitori nkan yi ati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, nwọn si pada lati lọ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

25. Nigbana ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu li oke Efraimu o si ngbe inu rẹ̀; o si jade lati ibẹ lọ, o si kọ́ Penueli.

26. Jeroboamu si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Nisisiyi ni ijọba na yio pada si ile Dafidi:

27. Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati ṣe irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalemu, nigbana li ọkàn awọn enia yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mi, nwọn o si tun pada tọ̀ Rehoboamu, ọba Juda lọ.

28. Ọba si gbìmọ, o si ya ẹgbọ̀rọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, O pọ̀ju fun nyin lati mã goke lọ si Jerusalemu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá!

29. O si gbe ọkan kalẹ ni Beteli, ati ekeji li o fi si Dani.

30. Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ: nitori ti awọn enia lọ lati sìn niwaju ọkan, ani titi de Dani.

31. O si kọ́ ile ibi giga wọnni, o si ṣe alufa lati inu awọn enia, ti kì iṣe inu awọn ọmọ Lefi.