18. A ko ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikọse alejò yi?
19. O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.
20. Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi:
21. Bẹ̃ni nwọn kì yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin.
22. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ọjọ mbọ̀, nigbati ẹnyin o fẹ lati ri ọkan ninu ọjọ Ọmọ-enia, ẹnyin kì yio si ri i.
23. Nwọn o si wi fun nyin pe, Wo o nihin; tabi wo o lọhun: ẹ má lọ, ẹ máṣe tẹle wọn.
24. Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ li apakan labẹ ọrun, ti isi mọlẹ li apa keji labẹ ọrun: bẹ̃li Ọmọ-enia yio si ri li ọjọ rẹ̀.
25. Ṣugbọn kò le ṣaima kọ́ jìya ohun pipo, ki a si kọ̀ ọ lọdọ iran yi.
26. Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹ̃ni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia.
27. Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ̀ inu ọkọ̀ lọ, kíkun omi si de, o si run gbogbo wọn.
28. Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Loti; nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn nrà, nwọn ntà, nwọn ngbìn, nwọn nkọle;
29. Ṣugbọn li ọjọ na ti Loti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ̀ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn.
30. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ-enia yio farahàn.
31. Li ọjọ na, eniti o ba wà lori ile, ti ẹrù rẹ̀ si mbẹ ni ile, ki o máṣe sọkalẹ lati wá kó o; ẹniti o ba si wà li oko, ki o máṣe pada sẹhin.
32. Ẹ ranti aya Loti.
33. Ẹnikẹni ti o ba nwá ati gbà ẹmi rẹ̀ là yio sọ ọ nù; ẹnikẹni ti o ba si sọ ọ nù yio gbà a là.
34. Mo wi fun nyin, li oru ọjọ na, enia meji yio wà lori akete kan; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.
35. Enia meji yio si ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.
36. Enia meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.