Yorùbá Bibeli

Luk 14:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati o wọ̀ ile ọkan ninu awọn olori Farisi lọ li ọjọ isimi lati jẹun, nwọn si nṣọ ọ.

2. Si kiyesi i, ọkunrin kan ti o li asunkun mbẹ niwaju rẹ̀.

3. Jesu si dahùn o wi fun awọn amofin ati awọn Farisi pe, O ha tọ́ lati mu-ni larada li ọjọ isimi, tabi kò tọ?

4. Nwọn si dakẹ. O si mu u, o mu u larada, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ;

5. O si dahùn o wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti kẹtẹkẹtẹ tabi malu rẹ̀ yio bọ sinu ihò, ti kì yio si fà a soke lojukanna li ọjọ isimi?

6. Nwọn kò si le da a li ohùn mọ́ si nkan wọnyi.

7. O si pa owe kan fun awọn ti a pè wá jẹun, nigbati o wò bi nwọn ti nyàn ipò ọlá; o si wi fun wọn pe,

8. Nigbati ẹnikan ba pè ọ wá si ibi iyawo, máṣe joko ni ipò ọlá; ki o ma ba jẹ pe, a pè ẹniti o li ọlá jù ọ lọ.

9. Nigbati ẹniti o pè ọ ati on ba de, a si wi fun ọ pe, Fun ọkunrin yi li àye; iwọ a si wa fi itiju mu ipò ẹhin.

10. Ṣugbọn nigbati a ba pè ọ, lọ ki o si joko ni ipò ẹhin; nigbati ẹniti o pè ọ ba de, ki o le wi fun ọ pe, Ọrẹ́, bọ́ soke: nigbana ni iwọ o ni iyin li oju awọn ti o ba ọ joko ti onjẹ.

11. Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, li a o si gbéga.

12. Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ.

13. Ṣugbọn nigbati iwọ ba se àse, pè awọn talakà, awọn alabùkù arùn, awọn amukun, ati awọn afọju:

14. Iwọ o si jẹ alabukun fun; nitori nwọn kò ni ohun ti nwọn o fi san a fun ọ: ṣugbọn a o san a fun ọ li ajinde awọn olõtọ.