Yorùbá Bibeli

Joh 18:8-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Jesu dahùn pe, Mo ti wi fun nyin pe, emi niyi: njẹ bi emi li ẹ ba nwá, ẹ jẹ ki awọn wọnyi mã lọ:

9. Ki ọ̀rọ nì ki o le ṣẹ, eyi ti o wipe, Awọn ti iwọ fifun mi, emi kò sọ ọ̀kan nù ninu wọn.

10. Nigbana ni Simoni Peteru ẹniti o ni idà, o fà a yọ, o si ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtun rẹ̀ sọnù. Orukọ iranṣẹ na ama jẹ Malku.

11. Nitorina Jesu wi fun Peteru pe, Tẹ̀ idà rẹ bọ inu àkọ rẹ̀: ago ti Baba ti fifun mi, emi ó ṣe alaimu u bi?

12. Nigbana li ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati olori ẹṣọ́, ati awọn onṣẹ awọn Ju mu Jesu, nwọn si dè e.

13. Nwọn kọ́ fa a lọ sọdọ Anna; nitori on ni iṣe ana Kaiafa, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na.

14. Kaiafa sá ni iṣe, ẹniti o ti ba awọn Ju gbìmọ̀ pe, o ṣanfani ki enia kan kú fun awọn enia.

15. Simoni Peteru si ntọ̀ Jesu lẹhin, ati ọmọ-ẹhin miran kan: ọmọ-ẹhin na jẹ ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o si ba Jesu wọ̀ afin olori alufa lọ.

16. Ṣugbọn Peteru duro li ẹnu-ọ̀na lode. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran nì, ti iṣe ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o jade lọ, o si ba oluṣọna na sọ ọ, o si mu Peteru wọle.

17. Nigbana li ọmọbinrin na ti nṣọ ẹnu-ọ̀na wi fun Peteru pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ọkunrin yi bi? O wipe, Emi kọ́.

18. Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.

19. Nigbana li olori alufa bi Jesu lẽre niti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati niti ẹkọ́ rẹ̀.

20. Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ.