Yorùbá Bibeli

Joṣ 24:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun.

2. Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa.

3. Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki.

4. Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti.

5. Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade.

6. Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa.