Yorùbá Bibeli

2. Sam 6:9-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá?

10. Dafidi kò si fẹ mu apoti-ẹri Oluwa sọdọ rẹ̀ si ilu Dafidi: ṣugbọn Dafidi si mu u yà si ile Obedi-Edomu ara Gati.

11. Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀.

12. A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀.

13. O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ.

14. Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.

15. Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.

16. Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.

17. Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa.

18. Dafidi si pari iṣẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na, o si sure fun awọn enia na li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun.

19. O si pin fun gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo ọpọ enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin; fun olukuluku iṣu akara kan ati ẹkirí ẹran kan, ati akara didun kan. Gbogbo awọn enia na si tuka lọ, olukuluku si ile rẹ̀.

20. Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ!

21. Dafidi si wi fun Mikali pe, Niwaju Oluwa ni, ẹniti o yàn mi fẹ jù baba rẹ lọ, ati ju gbogbo idile rẹ̀ lọ, lati fi emi ṣe olori awọn enia Oluwa, ani lori Israeli, emi o si ṣire niwaju Oluwa.

22. Emi o si tun rẹ̀ ara mi silẹ jù bẹ̃ lọ, emi o si ṣe alainiyìn loju ara mi, ati loju awọn iranṣẹbinrin wọnni ti iwọ wi, lọdọ wọn na li emi o si li ogo.

23. Mikali ọmọbinrin Saulu kò si bi ọmọ, titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀.