Yorùbá Bibeli

2. Sam 2:11-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba ni Hebroni lori ile Juda jẹ ọdun meje pẹlu oṣù mẹfa.

12. Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni.

13. Joabu ọmọ Seruia, ati awọn iranṣẹ Dafidi si jade, nwọn si jọ pade nibi adagun Gibeoni: nwọn si joko, ẹgbẹ kan li apa ihin adagun, ẹgbẹ keji li apa keji adagun.

14. Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ta pọrọ́ niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki wọn ki o dide.

15. Nigbana li awọn mejila ninu ẹya Benjamini ti iṣe ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu dide, nwọn si kọja siha keji; mejila ninu awọn ọmọ Dafidi si dide.

16. Olukuluku wọn si di ọmọnikeji rẹ̀ li ori mu, olukuluku si tẹ idà rẹ̀ bọ ẹnikeji rẹ̀ ni ihà: nwọn si jọ ṣubu lulẹ: nitorina li a si ṣe npe orukọ ibẹ na ni Helkatihassurimu, ti o wà ni Gibeoni.

17. Ijà na si kan gidigidi ni ijọ na, a si le Abneri ati awọn ọkunrin Israeli niwaju awọn ọmọ Dafidi.

18. Awọn ọmọ Seruia mẹtẹta si mbẹ nibẹ, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fẹrẹ bi ẹsẹ agbọnrin ti o wà ni pápa.

19. Asaheli si nlepa Abneri; bi on ti nlọ kò si yipada si ọwọ ọtun, tabi si ọwọ́ osì lati ma tọ Abneri lẹhin.

20. Nigbana ni Abneri boju wo ẹhin rẹ̀, o si bere pe, Iwọ Asaheli ni? On si dahùn pe, Emi ni.

21. Abneri si wi fun u pe, Iwọ yipada si apakan si ọwọ́ ọtun rẹ, tabi si osì rẹ, ki iwọ ki o si di ọkan mu ninu awọn ọmọkunrin, ki o si mu ihamọra rẹ̀. Ṣugbọn Asaheli kọ̀ lati pada lẹhin rẹ̀.

22. Abneri si tun wi fun Asaheli pe, Pada lẹhin mi, ẽṣe ti emi o fi lu ọ bolẹ? bawo li emi o ti ṣe gbe oju soke si Joabu arakunrin rẹ?