Yorùbá Bibeli

2. Sam 2:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe lẹhin eyi, Dafidi si bere lọwọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke lọ si ọkan ni ilu Juda wọnni bi? Oluwa si wi fun u pe, Goke lọ: Dafidi si wipe, niha ibo ni ki emi ki o lọ? On si wipe, Ni Hebroni.

2. Dafidi si goke lọ si ibẹ ati awọn obinrin rẹ̀ mejeji pẹlu, Ahinoamu ara Jesreeli ati Abigaili obinrin Nabali ara Karmeli.

3. Dafidi si mu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ goke, olukuluku ton ti ara ile rẹ̀: nwọn si joko ni ilu Hebroni wọnni.

4. Awọn ọkunrin Juda si wá, nwọn si fi Dafidi jọba nibẹ lori ile Juda. Nwọn si sọ fun Dafidi pe, Awọn ọkunrin Jabeṣi Gileadi li o sinkú Saulu.

5. Dafidi si ran onṣẹ si awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi o si wi fun wọn pe, Alabukun fun li ẹnyin lati ọwọ́ Oluwa wá, bi ẹnyin ti ṣe õre yi si oluwa nyin, si Saulu, ani ti ẹ fi sinkú rẹ̀.

6. Njẹ ki Oluwa ki o ṣe ore ati otitọ fun nyin: emi na yio si san ore yi fun nyin, nitori ti ẹnyin ṣe nkan yi.

7. Njẹ ẹ si mu ọwọ́ nyin le, ki ẹ si jẹ ẹni-alagbara: nitoripe Saulu oluwa nyin ti kú, ile Juda si ti fi àmi-ororo yàn mi li ọba wọn.

8. Ṣugbọn Abneri ọmọ Neri olori ogun Saulu si mu Iṣboṣeti ọmọ Saulu, o si mu u kọja si Mahanaimu;

9. On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli.

10. Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jẹ ẹni ogoji ọdun nigbati o bẹrẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba li ọdun meji. Ṣugbọn idile Juda ntọ̀ Dafidi lẹhin.

11. Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba ni Hebroni lori ile Juda jẹ ọdun meje pẹlu oṣù mẹfa.

12. Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni.