Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 8:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. O si ṣe ni ijọ keji ni o mu aṣọ ti o nipọn, o kì i bọ̀ omi, o si tẹ́ ẹ le oju rẹ̀, bẹ̃li o kú. Hasaeli si jọba nipò rẹ̀.

16. Ati li ọdun karun Joramu, ọmọ Ahabu ọba Israeli, Jehoṣafati jẹ ọba Juda: nigbana Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

17. Ẹni ọdun mejilelọgbọn li o jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu.

18. O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, bi ile Ahabu ti ṣe: nitori ọmọbinrin Ahabu li o nṣe aya rẹ̀; on si ṣe ibi niwaju Oluwa.

19. Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa Juda run, nitori Dafidi iranṣẹ rẹ̀, bi o ti ṣe ileri fun u, lati fun u ni imọlẹ ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọjọ gbogbo.

20. Li ọjọ rẹ̀ ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro li abẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn.

21. Bẹ̃ni Joramu rekọja siha Sairi, ati gbogbo awọn kẹkẹ́ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o yi i ka: ati awọn olori awọn kẹkẹ́: awọn enia si sá wọ inu agọ wọn.

22. Bẹ̃ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda titi o fi di oni yi. Nigbana ni Libna ṣọ̀tẹ li akokò kanna.

23. Iyokù iṣe Joramu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?