Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 8:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje.

2. Obinrin na si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun na: on si lọ pẹlu ile rẹ̀, nwọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọdun meje.

3. O si ṣe lẹhin ọdun meje, ni obinrin na pada bọ̀ lati ilẹ awọn ara Filistia: on si jade lọ lati kepè ọba nitori ile rẹ̀ ati nitori ilẹ rẹ̀.

4. Ọba si mba Gehasi iranṣẹ enia Ọlọrun na sọ̀rọ, wipe, Mo bẹ̀ ọ, sọ gbogbo ohun nla, ti Eliṣa ti ṣe fun mi.

5. O si ṣe bi o ti nrò fun ọba bi o ti sọ okú kan di ãyè, si kiyesi i, obinrin na, ẹniti a sọ ọmọ rẹ̀ di ãyè kepè ọba nitori ilẹ rẹ ati nitori ile rẹ̀. Gehasi si wipe, Oluwa mi, ọba, eyi li obinrin na, eyi si li ọmọ rẹ̀ ti Eliṣa sọ di ãyè.

6. Nigbati ọba si bère lọwọ obinrin na, o rohin fun u. Ọba si yàn iwẹ̀fa kan fun u, wipe, Mu ohun gbogbo ti iṣe ti rẹ̀ pada fun u, ati gbogbo erè oko lati ọjọ ti o ti fi ilẹ silẹ titi di isisiyi.

7. Eliṣa si wá si Damasku; Benhadadi ọba Siria si nṣe aisàn; a si sọ fun u, wipe, Enia Ọlọrun de ihinyi.

8. Ọba si wi fun Hasaeli pe, Mu ọrẹ lọwọ rẹ, si lọ ipade enia Ọlọrun na, ki o si bère lọwọ Oluwa lọdọ rẹ̀, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi?

9. Bẹ̃ni Hasaeli lọ ipade rẹ̀, o si mu ọrẹ li ọwọ rẹ̀, ani ninu gbogbo ohun rere Damasku, ogoji ẹrù ibakasiẹ, o si de, o si duro niwaju rẹ̀, o si wipe, Ọmọ rẹ Benhadadi ọba Siria rán mi si ọ, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi?

10. Eliṣa si wi fun u pe, Lọ, ki o si sọ fun u pe, Iwọ iba sàn nitõtọ: ṣugbọn Oluwa ti fi hàn mi pe, nitõtọ on o kú.

11. On si tẹ̀ oju rẹ̀ mọ ọ gidigidi, titi oju fi tì i; enia Ọlọrun na si sọkun.

12. Hasaeli si wipe, Ẽṣe ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahùn pe, Nitoriti mo mọ̀ ibi ti iwọ o ṣe si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi idà pa, iwọ o si fọ́ ọmọ wẹwẹ́ wọn tútu, iwọ o si là inu awọn aboyun wọn.