Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 7:16-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Awọn enia si jade lọ, nwọn si kó ibùdo awọn ara Siria. Bẹ̃ni a ntà oṣùwọn iyẹ̀fun kikunná kan ni ṣekeli kan, ati oṣuwọn barle meji ni ṣekeli kan, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

17. Ọba si yàn ijòye na, lọwọ ẹniti o nfi ara tì, lati ṣe itọju ẹnu bodè: awọn enia si tẹ̀ ẹ mọlẹ ni bodè, o si kú, bi enia Ọlọrun na ti wi, ẹniti o sọ̀rọ nigbati ọba sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá.

18. O si ṣe, bi enia Ọlọrun na ti sọ fun ọba, wipe, Oṣùwọn barle meji fun ṣekeli kan, ati òṣuwọn iyẹfun kikunná kan, fun ṣekeli kan, yio wà ni iwòyi ọla ni ẹnu bodè Samaria:

19. Ijòye na si da enia Ọlọrun na li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, nisisiyi, bi Oluwa tilẹ ṣe ferese li ọrun, iru nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.

20. Bẹ̃li o si ri fun u: nitori awọn enia tẹ̀ ẹ mọlẹ ni ẹnu bodè, o si kú.