Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 6:2-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Jẹ ki awa ki o lọ, awa bẹ̀ ọ, si Jordani, ki olukulùku wa ki o mu iti igi kọ̃kan wá, si jẹ ki awa ki o ṣe ibikan, ti awa o ma gbe. On si dahùn wipe, Ẹ mã lọ.

3. Ẹnikan si wipe, Ki o wu ọ, emi bẹ̀ ọ, lati ba awọn iranṣẹ rẹ lọ. On si dahùn pe, Emi o lọ.

4. Bẹ̃li o ba wọn lọ. Nigbati nwọn si de Jordani, nwọn ké igi.

5. O si ṣe, bi ẹnikan ti nké iti-igi, ãke yọ sinu omi: o si kigbe, o si wipe, Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rẹ̀ ni.

6. Enia Ọlọrun si wipe, Nibo li o bọ́ si? O si fi ibẹ hàn a. On si ké igi kan, o si sọ́ ọ sinu rẹ̀; irin na si fó soke.

7. Nitorina o wipe, Mu u. On si nà ọwọ rẹ̀, o si mu u.

8. Nigbana ni ọba Siria mba Israeli jagun, o si ba awọn iranṣẹ rẹ̀ gbèro wipe, Ni ibi bayibayi ni ibùba mi yio gbe wà.

9. Enia Ọlọrun si ranṣẹ si ọba Israeli wipe Kiye sara, ki iwọ ki o máṣe kọja si ibi bayi; nitori nibẹ ni awọn ara Siria ba si.

10. Ọba Israeli si ranṣẹ si ibẹ na ti enia Ọlọrun ti sọ fun u, ti o si ti kilọ fun u, o si gbà ara rẹ̀ nibẹ, kì iṣe nigbà kan tabi nigba meji.

11. Nitorina li ọkàn ọba Siria bajẹ gidigidi nitori nkan yi: o si pè awọn iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin kì yio ha fihan mi, tani ninu wa ti o nṣe ti ọba Israeli?

12. Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kò si ẹnikan, oluwa mi, ọba; bikoṣe Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israeli, ni nsọ fun ọba Israeli gbogbo ọ̀rọ ti iwọ nsọ ninu iyẹ̀wu rẹ.

13. On si wipe, Ẹ lọ iwò ibi ti on gbe wà, ki emi o le ranṣẹ lọ mu u wá. A si sọ fun u, wipe, Wò o, o wà ni Dotani.

14. Nitorina li o ṣe rán awọn ẹṣin ati kẹkẹ́ ati ogun nla sibẹ: nwọn si de li oru, nwọn si yi ilu na ka.

15. Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?

16. On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ.