Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 3:21-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nigbati gbogbo ara Moabu gbọ́ pe, awọn ọba gòke wá lati ba wọn jà, nwọn kó gbogbo awọn ti o le hamọra ogun jọ, ati awọn ti o dagba jù wọn lọ, nwọn si duro li eti ilẹ wọn.

22. Nwọn si dide li owurọ̀, õrùn si ràn si oju omi na, awọn ara Moabu si ri omi na li apakeji, o pọn bi ẹ̀jẹ:

23. Nwọn si wipe, Ẹ̀jẹ li eyi: awọn ọba na run: nwọn si ti pa ara wọn; njẹ nisisiyi, Moabu, dide si ikogun.

24. Nigbati nwọn si de ibùdo Israeli, awọn ọmọ Israeli dide, nwọn si kọlù awọn ara Moabu, nwọn si sa kuro niwaju wọn: nwọn si wọ inu rẹ̀, nwọn si pa Moabu run.

25. Nwọn si wó gbogbo ilu, olukulùku si jù okuta tirẹ̀ si gbogbo oko rere, nwọn si kún wọn; nwọn si dí gbogbo kanga omi, nwọn si bẹ́ gbogbo igi rere: ni Kirharaseti ni nwọn fi kiki awọn okuta rẹ̀ silẹ ṣugbọn awọn oni-kànakana yi i ka, nwọn si kọlù u.

26. Nigbati ọba Moabu ri i pe ogun na le jù fun on, o mu ẹ̃dẹgbẹrin ọkunrin ti o fà idà yọ pẹlu rẹ̀, lati là ogun ja si ọdọ ọba Edomu: ṣugbọn nwọn kò le ṣe e.

27. Nigbana li o mu akọbi ọmọ rẹ̀ ti iba jọba ni ipò rẹ̀, o si fi i rubọ sisun li ori odi. Ibinu nla si wà si Israeli: nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, nwọn si pada si ilẹ wọn.