Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 25:4-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ.

5. Ogun awọn ara Kaldea si lepa ọba, nwọn si ba a ni pẹ̀tẹlẹ Jeriko: gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.

6. Bẹ̃ni nwọn mu ọba, nwọn si mu u gòke lọ si ọdọ ọba Babeli ni Ribla; nwọn si sọ ọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.

7. Nwọn si pa awọn ọmọ Sedekiah li oju rẹ̀, nwọn si fọ Sedekiah li oju, nwọn si fi ẹwọn idẹ dè e, nwọn si mu u lọ si Babeli.

8. Ati li oṣù karun, li ọjọ keje oṣù, ti iṣe ọdun ikọkandilogun Nebukadnessari ọba, ọba Babeli, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ, iranṣẹ ọba Babeli, wá si Jerusalemu:

9. O si fi ile Oluwa joná, ati ile ọba, ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile enia nla li o fi iná sun.

10. Gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti o wà lọdọ olori ẹ̀ṣọ, si wó odi Jerusalemu palẹ yika kiri.

11. Ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ati awọn isansa ti o ya tọ̀ ọba, Babeli lọ, pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ti o kù, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ kó lọ.

12. Ṣugbọn olori ẹ̀ṣọ fi awọn talakà ilẹ na silẹ, lati mã ṣe alabojuto àjara ati lati mã ṣe aroko.

13. Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ ni ile Oluwa, ati ijoko wọnni, ati agbada-nla idẹ ti o wà ni ile Oluwa, li awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó idẹ wọn lọ si Babeli.

14. Ati ikòko wọnni, ati ọkọ wọnni, ati alumagàji fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun-èlo wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ, ni nwọn kó lọ.

15. Ati ohun ifọnná wọnni, ati ọpọ́n wọnni, eyi ti iṣe ti wura, ni wura, ati eyi ti iṣe ti fadakà ni fadakà, ni olori ẹ̀ṣọ kó lọ.

16. Awọn ọ̀wọn meji, agbada-nla kan, ati ijoko wọnni ti Solomoni ti ṣe fun ile Oluwa; idẹ ni gbogbo ohun-èlo wọnyi, alaini ìwọn ni.