Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 19:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Nitorina ni awọn olugbe wọn fi ṣe alainipa, a daiyàfo wọn nwọn si dãmu; nwọn dàbi koriko igbẹ́, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko li ori ile, ati bi ọkà ti o rẹ̀ danù ki o to dàgba soke.

27. Ṣugbọn emi mọ̀ ijoko rẹ, ati ijadelọ rẹ, ati bibọ̀ rẹ, ati ikannu rẹ si mi.

28. Nitori ikánnu rẹ si mi ati irera rẹ de eti mi, nitorina li emi o fi ìwọ̀ mi kọ́ ọ ni imu, ati ijanu mi si ẹnu rẹ, emi o si yi ọ pada si ọ̀na na ti iwọ ti ba wá.

29. Eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun ni, ati li ọdun keji eyiti o hù ninu ọkanna; ati li ọdun kẹta ẹ fun irúgbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba ajara, ki ẹ si jẹ eso rẹ̀.

30. Iyokù ile Juda ti o salà yio si tún ta gbòngbo si isàlẹ, yio si so eso li òke.

31. Nitori lati Jerusalemu li awọn iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o salà lati oke Sioni jade: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni yio ṣe eyi.