Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 18:27-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ṣugbọn Rabṣake sọ fun wọn pe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ, ati si ọ, lati sọ ọ̀rọ wọnyi bi? kò ṣepe awọn ọkunrin ti o joko lori odi li o rán mi si, ki nwọn ki o le jẹ igbẹ́ ara wọn, ati ki nwọn ki o le mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?

28. Nigbana ni Rabṣake duro, o si kigbe li ohùn rara li ède Juda o si sọ wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria:

29. Bayi li ọba wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori kì yio le gbà nyin kuro lọwọ rẹ̀:

30. Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a kì yio si fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.

31. Ẹ máṣe fi eti si ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Fi ẹbùn wá oju rere mi, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá, ki olukuluku nyin ki o si mã jẹ ninu àjarà rẹ̀, ati olukuluku ninu igi ọ̀pọtọ rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si mu omi ninu àmu rẹ̀:

32. Titi emi o fi wá mu nyin kuro lọ si ilẹ bi ti ẹnyin tikara nyin, si ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọgbà ajara, ilẹ ororo olifi ati ti oyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ má ba kú: ki ẹ má si fi eti si ti Hesekiah, nigbati o ba ntàn nyin wipe, Oluwa yio gbà wa.

33. Ọkan ninu awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ti igbà ilẹ rẹ̀ kuro lọwọ ọba Assiria ri bi?

34. Nibo li awọn oriṣa Hamati, ati Arpadi gbe wà? Nibo li awọn oriṣa Sefarfaimu, Hena, ati Ifa gbe wà? Nwọn ha gbà Samaria kuro lọwọ mi bi?

35. Tani ninu gbogbo awọn oriṣa ilẹ wọnni ti o gbà ilẹ wọn kuro lọwọ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro lọwọ mi?

36. Ṣugbọn awọn enia pa ẹnu wọn mọ́, nwọn kò si da a li ohun ọ̀rọ kan: nitori aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a li ohùn.

37. Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah ti iṣe olori ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu akọwe-iranti wá sọdọ Hesekiah, ti awọn, ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.