Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 18:22-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ṣugbọn bi ẹnyin ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on ha kọ li ẹniti Hesekiah ti mu awọn ibi giga rẹ̀, ati awọn pẹpẹ rẹ̀ kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, Ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi ni Jerusalemu?

23. Njẹ nisisiyi, Mo bẹ̀ ọ, ba oluwa mi ọba Assiria ṣe adehun, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba lè ni enia to lati gùn wọn.

24. Njẹ bawo ni iwọ o ha ti ṣe le yi oju balogun kan ti o kere jùlọ pada ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si gbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́ ati fun ẹlẹṣin?

25. Emi ha dẹhin Oluwa gòke wá nisisiyi si ibi yi lati pa a run? Oluwa wi fun mi pe, Gòke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run.

26. Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah, ati Ṣebna, ati Joa wi fun Rabṣake pe, Emi bẹ̀ ọ, ba awọn iranṣẹ rẹ sọ̀rọ li ède Siria; nitoriti awa gbọ́ ọ: ki o má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Juda li leti awọn enia ti mbẹ lori odi.

27. Ṣugbọn Rabṣake sọ fun wọn pe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ, ati si ọ, lati sọ ọ̀rọ wọnyi bi? kò ṣepe awọn ọkunrin ti o joko lori odi li o rán mi si, ki nwọn ki o le jẹ igbẹ́ ara wọn, ati ki nwọn ki o le mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?

28. Nigbana ni Rabṣake duro, o si kigbe li ohùn rara li ède Juda o si sọ wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria:

29. Bayi li ọba wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori kì yio le gbà nyin kuro lọwọ rẹ̀:

30. Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a kì yio si fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.

31. Ẹ máṣe fi eti si ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Fi ẹbùn wá oju rere mi, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá, ki olukuluku nyin ki o si mã jẹ ninu àjarà rẹ̀, ati olukuluku ninu igi ọ̀pọtọ rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si mu omi ninu àmu rẹ̀: