Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 17:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ọba Assiria si ri ọ̀tẹ ninu Hoṣea: nitoriti o ti rán onṣẹ sọdọ So ọba Egipti, kò si mu ọrẹ fun ọba Assiria wá bi iti mã iṣe li ọdọdun; nitorina ni ọba Assiria há a mọ, o si dè e ni ile tubu.

5. Nigbana ni ọba Assiria gòke wá si gbogbo ilẹ na, o si gòke lọ si Samaria, o si dotì i li ọdun mẹta.

6. Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.

7. O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran.

8. Ti nwọn si nrìn ninu ilana awọn keferi, ti Oluwa ti le jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, ati ti awọn ọba Israeli, ti nwọn ti ṣe.

9. Awọn ọmọ Israeli si ṣe ohun ikọ̀kọ ti kò tọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kọ́ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.

10. Nwọn si gbé awọn ere kalẹ, nwọn si dá ere oriṣa si lori òke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo:

11. Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi ti Oluwa kó lọ niwaju wọn ti ṣe; nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu Oluwa soke.

12. Nitoriti nwọn sìn oriṣa wọnni, eyiti Oluwa ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣe nkan yi.

13. Sibẹ Oluwa jẹri si Israeli, ati si Juda, nipa ọwọ gbogbo awọn woli, ati gbogbo awọn ariran, wipe, Ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ́, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, ti mo rán si nyin nipa ọwọ awọn woli iranṣẹ mi.

14. Sibẹ nwọn kò fẹ igbọ́, ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, gẹgẹ bi ọrùn awọn baba wọn, ti kò gbà Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́.