Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 17:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kejila Ahasi ọba Juda ni Hoṣea ọmọ Ela bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, lori Israeli li ọdun mẹsan.

2. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi awọn ọba Israeli ti o ti wà ṣãju rẹ̀.

3. On ni Ṣalamaneseri ọba Assiria gòke tọ̀ wá; Hoṣea si di iranṣẹ rẹ̀, o si ta a li ọrẹ.

4. Ọba Assiria si ri ọ̀tẹ ninu Hoṣea: nitoriti o ti rán onṣẹ sọdọ So ọba Egipti, kò si mu ọrẹ fun ọba Assiria wá bi iti mã iṣe li ọdọdun; nitorina ni ọba Assiria há a mọ, o si dè e ni ile tubu.

5. Nigbana ni ọba Assiria gòke wá si gbogbo ilẹ na, o si gòke lọ si Samaria, o si dotì i li ọdun mẹta.

6. Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.

7. O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran.