Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 22:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ọba Israeli si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin ha mọ̀ pe, tiwa ni Ramoti-Gileadi, awa si dakẹ, a kò si gbà a kuro lọwọ ọba Siria?

4. O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.

5. Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Mo bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa li oni yi.

6. Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

7. Jehoṣafati si wipe, Kò si woli Oluwa kan nihin pẹlu, ti awa iba bère lọwọ rẹ̀?

8. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃.

9. Ọba Israeli si pè iwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah, ọmọ Imla, ki o yara wá.

10. Ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda joko olukulùku lori itẹ́ rẹ̀, nwọn wọ̀ aṣọ igunwa wọn ni ita ẹnu-bode Samaria, gbogbo awọn woli na si nsọtẹlẹ niwaju wọn.

11. Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.

12. Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe: Goke lọ si Ramoti-Gileadi, ki o si ṣe rere: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

13. Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnu kanna ni ọ̀rọ awọn woli fi jẹ rere fun ọba: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọ̀rọ ọkan ninu wọn, ki o si sọ rere.

14. Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti wà, ohun ti Oluwa ba sọ fun mi li emi o sọ.

15. Bẹ̃ni o de ọdọ ọba. Ọba si wi fun u pe, Mikaiah, ki awa o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki a jọwọ rẹ̀? O si da a lohùn pe, Lọ, ki o si ṣe rere: nitori Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

16. Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bu pe, ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikoṣe otitọ li orukọ Oluwa?