Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 22:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌDUN mẹta si rekọja laisi ogun lãrin Siria ati lãrin Israeli.

2. O si ṣe li ọdun kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda sọkalẹ tọ ọba Israeli wá.

3. Ọba Israeli si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin ha mọ̀ pe, tiwa ni Ramoti-Gileadi, awa si dakẹ, a kò si gbà a kuro lọwọ ọba Siria?

4. O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.

5. Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Mo bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa li oni yi.

6. Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

7. Jehoṣafati si wipe, Kò si woli Oluwa kan nihin pẹlu, ti awa iba bère lọwọ rẹ̀?

8. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃.

9. Ọba Israeli si pè iwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah, ọmọ Imla, ki o yara wá.

10. Ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda joko olukulùku lori itẹ́ rẹ̀, nwọn wọ̀ aṣọ igunwa wọn ni ita ẹnu-bode Samaria, gbogbo awọn woli na si nsọtẹlẹ niwaju wọn.

11. Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.