Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 21:19-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ.

20. Ahabu si wi fun Elijah pe, Iwọ ri mi, Iwọ ọta mi? O si dahùn wipe, Emi ri ọ; nitoriti iwọ ti tà ara rẹ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa.

21. Kiyesi i, Emi o mu ibi wá si ori rẹ, emi o si mu iran rẹ kuro, emi o si ke kuro lọdọ Ahabu, gbogbo ọmọde ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ, ati omnira ni Israeli.

22. Emi o si ṣe ile rẹ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa, ọmọ Ahijah, nitori imunibinu ti iwọ ti mu mi binu, ti iwọ si mu ki Israeli ki o dẹ̀ṣẹ.

23. Ati niti Jesebeli pẹlu Oluwa sọ wipe, Awọn ajá yio jẹ Jesebeli ninu yàra Jesreeli.

24. Ẹni Ahabu ti o kú ni ilu, ni awọn ajá o jẹ; ati ẹniti o kú ni igbẹ ni awọn ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ.

25. Ṣugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rẹ̀ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rẹ̀ ntì.

26. O si ṣe ohun irira gidigidi ni titọ̀ oriṣa lẹhin, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awọn ara Amori ti ṣe, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.

27. O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si gbàwẹ, o si dubulẹ ninu aṣọ ọ̀fọ, o si nlọ jẹ́.

28. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe,

29. Iwọ ri bi Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi? Nitori ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi, emi kì yio mu ibi na wá li ọjọ rẹ̀: li ọjọ ọmọ rẹ̀ li emi o mu ibi na wá sori ile rẹ̀.