Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 2:34-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Benaiah, ọmọ Jehoiada, si goke, o si kọlù u, ó si pa a: a si sin i ni ile rẹ̀ li aginju.

35. Ọba si fi Benaiah, ọmọ Jehoiada, jẹ olori-ogun ni ipò rẹ̀, ati Sadoku alufa ni ọba fi si ipò Abiatari.

36. Ọba si ranṣẹ, o si pe Ṣimei, o si wi fun u pe, Kọ́ ile fun ara rẹ ni Jerusalemu, ki o si ma gbe ibẹ̀, ki o má si ṣe jade lati ibẹ lọ si ibikibi.

37. Yio si ṣe li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si kọja odò Kidroni, ki iwọ mọ̀ dajudaju pe, Kikú ni iwọ o kú; ẹ̀jẹ rẹ yio wà lori ara rẹ.

38. Ṣimei si wi fun ọba pe, Ọrọ na dara, gẹgẹ bi oluwa mi ọba ti wi, bẹ̃ gẹgẹ ni iranṣẹ rẹ yio ṣe. Ṣimei si gbe Jerusalemu li ọjọ pupọ.

39. O si ṣe lẹhin ọdun mẹta, awọn ọmọ-ọdọ Ṣimei meji si lọ sọdọ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati. Nwọn si rò fun Ṣimei pe, Wo o, awọn ọmọ-ọdọ rẹ mbẹ ni Gati.

40. Ṣimei si dide, o si di kẹtẹkẹtẹ ni gari, o si lọ, o si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ bọ̀ lati Gati.

41. A si rò fun Solomoni pe, Ṣimei ti lọ lati Jerusalemu si Gati, o si pada bọ̀.

42. Ọba si ranṣẹ, o si pè Ṣimei, o si wi fun u pe, emi kò ti mu ọ fi Oluwa bura, emi kò si ti fi ọ ṣe ẹlẹri, pe, Li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si rìn jade lọ nibikibi, ki iwọ ki o mọ̀ dajudaju pe, kikú ni iwọ o kú? iwọ si wi fun mi pe, Ọrọ na ti mo gbọ́, o dara.

43. Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ?

44. Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ.

45. A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai.