Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 13:2-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ.

3. O si fun wọn li àmi kan li ọjọ kanna wipe, Eyi li àmi ti Oluwa ti ṣe; Kiyesi i, pẹpẹ na yio ya, ẽru ti mbẹ lori rẹ̀ yio si danu.

4. O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọba gbọ́ ọ̀rọ enia Ọlọrun, ti o ti kigbe si pẹpẹ na, o wipe, Ẹ mu u. Ọwọ́ rẹ̀ ti o nà si i, si gbẹ, bẹ̃ni kò si le fa a pada sọdọ rẹ̀ mọ.

5. Pẹpẹ na si ya, ẽru na si danù kuro ninu pẹpẹ na, gẹgẹ bi àmi ti enia Ọlọrun ti fi fun u nipa ọ̀rọ Oluwa.

6. Ọba si dahùn, o si wi fun enia Ọlọrun na pe, Tù Oluwa Ọlọrun rẹ loju nisisiyi, ki o si gbadura fun mi, ki a ba le tun mu ọwọ́ mi bọ̀ sipo fun mi. Enia Ọlọrun na si tù Ọlọrun loju, a si tun mu ọwọ́ ọba bọ̀ sipo fun u, o si dàbi o ti wà ri.

7. Ọba si wi fun enia Ọlọrun na pe, Wá ba mi lọ ile, ki o si tù ara rẹ lara, emi o si ta ọ li ọrẹ.

8. Enia Ọlọrun na si wi fun ọba pe, Bi iwọ o ba fun mi ni idaji ile rẹ, emi kì yio ba ọ lọ ile, emi kì yio si jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kì yio si mu omi nihin yi.

9. Nitori bẹ̃ li a pa a laṣẹ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Máṣe jẹ onjẹ, má si ṣe mu omi, bẹ̃ni ki o má si ṣe pada li ọ̀na kanna ti o ba wá.

10. Bẹ̃ li o si ba ọ̀na miran lọ, kò si pada li ọ̀na na ti o gbà wá si Beteli.

11. Woli àgba kan si ngbe Beteli: ọmọ rẹ̀ de, o si rohin gbogbo iṣẹ ti enia Ọlọrun na ti ṣe li ọjọ na ni Beteli fun u: ọ̀rọ ti o sọ fun ọba nwọn si sọ fun baba wọn.

12. Baba wọn si wi fun wọn pe, Ọna wo li o gbà? Nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti ri ọ̀na ti enia Ọlọrun na gbà, ti o ti Juda wá.

13. O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u o si gùn u.

14. O si tẹ̀le enia Ọlọrun na lẹhin, o si ri i, o joko labẹ igi nla kan: o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun na ti o ti Juda wá? On si wipe, Emi ni.

15. O si wi fun u pe, Ba mi lọ ile, ki o si jẹ onjẹ.

16. On si wipe, Emi kò lè pada lọ pẹlu rẹ, bẹ̃ni emi kò lè ba ọ lọ: bẹ̃ni emi kì o jẹ onjẹ, emi kì o si mu omi pẹlu rẹ nihin yi.

17. Nitori ti a sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Iwọ kò gbọdọ jẹ onjẹ, iwọ kò si gbọdọ mu omi nibẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tun pada lọ nipa ọ̀na ti iwọ ba wá.

18. O si wi fun u pe, Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angeli si sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi. Ṣugbọn o purọ fun u.