Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 11:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O si ni ẽdẹgbẹrin obinrin, awọn ọmọ ọba, ati ọ̃dunrun alè, awọn aya rẹ̀ si yi i li ọkàn pada.

4. O si ṣe, nigbati Solomoni di arugbo, awọn obinrin rẹ̀ yi i li ọkàn pada si ọlọrun miran: ọkàn rẹ̀ kò si ṣe dede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rẹ̀.

5. Nitori Solomoni tọ Aṣtoreti lẹhin, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Milkomu, irira awọn ọmọ Ammoni.

6. Solomoni si ṣe buburu niwaju Oluwa, kò si tọ̀ Oluwa lẹhin ni pipé gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

7. Nigbana ni Solomoni kọ́ ibi giga kan fun Kemoṣi, irira Moabu, lori oke ti mbẹ niwaju Jerusalemu, ati fun Moleki, irira awọn ọmọ Ammoni.

8. Bẹ̃li o si ṣe fun gbogbo awọn ajeji obinrin rẹ̀, awọn ti nsun turari, ti nwọn si nrubọ fun oriṣa wọn.

9. Oluwa si binu si Solomoni, nitori ọkàn rẹ̀ yipada kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ara hàn a lẹrinmeji.

10. Ti o si paṣẹ fun u nitori nkan yi pe, Ki o má ṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin: ṣugbọn kò pa eyiti Oluwa fi aṣẹ fun u mọ́.