Yorùbá Bibeli

Eks 19:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ọwọkọwọ́ kò gbọdọ kàn a, bikoṣepe ki a sọ ọ li okuta, tabi ki a gún u pa nitõtọ; iba ṣe ẹranko iba ṣe enia, ki yio là a: nigbati ipè ba dún, ki nwọn ki o gùn oke wá.

14. Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn.

15. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin.

16. O si ṣe, li owurọ̀ ijọ́ kẹta, ni ãrá ati mànamána wà, ati awọsanma ṣíṣu dùdu lori òke na, ati ohùn ipè na si ndún kikankikan; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti o wà ni ibudó warìri.

17. Mose si mú awọn enia jade lati ibudó wá lati bá Ọlọrun pade; nwọn si duro ni ìha isalẹ oke na.

18. Oke Sinai si jẹ́ kìki ẽfi, nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rẹ̀ ninu iná: ẽfi na si goke bi ẽfi ileru, gbogbo oke na si mì tìtì.

19. O si ṣe ti ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji, Mose sọ̀rọ, Ọlọrun si fi ãrá da a li ohùn.

20. OLUWA si sọkalẹ wá si oke Sinai, lori oke na: OLUWA si pè Mose lori oke na; Mose si goke lọ.

21. OLUWA si wi fun Mose pe, Sọkalẹ, kìlọ fun awọn enia, ki nwọn ki o má ba yà sọdọ OLUWA lati bẹ̀ ẹ wò, ki ọ̀pọ ki o má ba ṣegbe ninu wọn.

22. Si jẹ ki awọn alufa pẹlu, ti o sunmọ OLUWA, ki o yà ara wọn si mimọ́, ki OLUWA ki o má ba kọlù wọn.

23. Mose si wi fun OLUWA pe, Awọn enia ki yio le wá sori oke Sinai: nitoriti iwọ ti kìlọ fun wa pe, Sọ agbàra yi oke na ká, ki o si yà a si mimọ́.

24. OLUWA si wi fun u pe, Lọ, sọkalẹ; ki iwọ ki o si goke wá, iwọ ati Aaroni pẹlu rẹ: ṣugbọn ki awọn alufa ati awọn enia ki o máṣe yà lati goke tọ̀ OLUWA wá, ki o má ba kọlù wọn.