Yorùbá Bibeli

Rom 5:8-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.

9. Melomelo si ni, ti a da wa lare nisisiyi nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, li a o gbà wa là kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ̀.

10. Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀.

11. Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa nṣogo ninu Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti awa ti ri ìlaja gbà nisisiyi.

12. Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀:

13. Nitori ki ofin ki o to de, ẹ̀ṣẹ ti wà li aiye; ṣugbọn a kò kà ẹ̀ṣẹ si ni lọrun nigbati ofin kò si.

14. Ṣugbọn ikú jọba lati igbà Adamu wá titi fi di igba ti Mose, ati lori awọn ti kò ṣẹ̀ bi afarawe irekọja Adamu, ẹniti iṣe apẹrẹ ẹniti mbọ̀.

15. Ṣugbọn kì iṣe bi ẹ̀ṣẹ bẹ̃ si li ẹ̀bun ọfẹ. Nitori bi nipa ẹ̀ṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ kú, melomelo li ore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹ̀bun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ.

16. Kì isi ṣe bi nipa ẹnikan ti o ṣẹ̀, li ẹ̀bun na: nitori idajọ ti ipasẹ ẹnikan wá fun idalẹbi ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ ti inu ẹ̀ṣẹ pupọ wá fun idalare.

17. Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ ọkunrin kan ikú jọba nipasẹ ẹnikanna; melomelo li awọn ti ngbà ọ̀pọlọpọ ore-ọfẹ ati ẹ̀bun ododo yio jọba ninu ìye nipasẹ ẹnikan, Jesu Kristi.