Yorùbá Bibeli

Rom 4:10-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni.

11. O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu:

12. Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla.

13. Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́.

14. Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara:

15. Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀.

16. Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa,

17. (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà;

18. Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri.

19. Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara:

20. Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun;

21. Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e.

22. Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u.

23. A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u,

24. Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú;

25. Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.