O. Daf

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Yorùbá Bibeli

O. Daf 26 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ẹni Rere

1. ṢE idajọ mi, Oluwa; nitori ti mo ti nrìn ninu ìwa titọ mi; emi ti gbẹkẹle Oluwa pẹlu; njẹ ẹsẹ mi kì yio yẹ̀.

2. Wadi mi, Oluwa, ki o si ridi mi; dán inu mi ati ọkàn mi wò.

3. Nitoriti iṣeun-ifẹ rẹ mbẹ niwaju mi: emi si ti nrìn ninu otitọ rẹ.

4. Emi kò ba ẹni asan joko, bẹ̃li emi kì yio ba awọn alayidayida wọle.

5. Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko.

6. Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.

7. Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ.

8. Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ.

9. Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, tabi ẹmi mi pẹlu awọn enia-ẹ̀jẹ.

10. Li ọwọ ẹniti ìwa-ìka mbẹ, ọwọ ọtún wọn si kún fun abẹtẹlẹ.

11. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o ma rìn ninu ìwatitọ mi: rà mi pada, ki o si ṣãnu fun mi.

12. Ẹsẹ mi duro ni ibi titẹju: ninu awọn ijọ li emi o ma fi ibukún fun Oluwa.