O. Daf

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Yorùbá Bibeli

O. Daf 145 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ìyìn

1. EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai.

2. Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai.

3. Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀.

4. Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ.

5. Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ.

6. Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ.

7. Nwọn o ma sọ̀rọ iranti ore rẹ pupọ̀-pupọ̀, nwọn o si ma kọrin ododo rẹ.

8. Olore-ọfẹ li Oluwa, o kún fun ãnu; o lọra lati binu, o si li ãnu pupọ̀.

9. Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo.

10. Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ.

11. Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ:

12. Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo,

13. Ijọba rẹ ijọba aiye-raiye ni, ati ijọba rẹ lati iran-diran gbogbo.

14. Oluwa mu gbogbo awọn ti o ṣubu ró; o si gbé gbogbo awọn ti o tẹriba dide.

15. Oju gbogbo enia nwò ọ; iwọ si fun wọn li onjẹ wọn li akokò rẹ̀.

16. Iwọ ṣi ọwọ rẹ, iwọ si tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alãye lọrùn.

17. Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo.

18. Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ.

19. Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn.

20. Oluwa da gbogbo awọn ti o fẹ ẹ si: ṣugbọn gbogbo enia buburu ni yio parun.

21. Ẹnu mi yio ma sọ̀rọ iyìn Oluwa: ki gbogbo enia ki o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́ lai ati lailai.