O. Daf

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Yorùbá Bibeli

O. Daf 143 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ìrànlọ́wọ́

1. OLUWA, gbọ́ adura mi, fi eti si ẹ̀bẹ mi; ninu otitọ rẹ dá mi lohùn ati ninu ododo rẹ.

2. Ki o má si ba ọmọ-ọdọ rẹ lọ sinu idajọ, nitori ti kò si ẹniti o wà lãye ti a o dalare niwaju rẹ.

3. Nitori ti ọta ti ṣe inunibini si ọkàn mi; o ti lù ẹmi mi bolẹ; o ti mu mi joko li òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.

4. Nitorina li ẹmi mi ṣe rẹ̀wẹsi ninu mi; òfo fò aiya mi ninu mi.

5. Emi ranti ọjọ atijọ; emi ṣe àṣaro iṣẹ rẹ gbogbo, emi nronu iṣẹ ọwọ rẹ.

6. Emi nà ọwọ mi si ọ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi bi ilẹ gbigbẹ.

7. Oluwa, gbọ́ temi nisisiyi; o rẹ̀ ọkàn mi tan; máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi, ki emi ki o má bà dabi awọn ti o lọ sinu ihò.

8. Mu mi gbọ́ iṣeun-ifẹ rẹ li owurọ; nitori iwọ ni mo gbẹkẹle: mu mi mọ̀ ọ̀na ti emi iba ma tọ̀; nitori mo gbé ọkàn mi soke si ọ.

9. Oluwa, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: ọdọ rẹ ni mo sa pamọ́ si.

10. Kọ́ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹju.

11. Oluwa, sọ mi di ãye nitori orukọ rẹ: ninu ododo rẹ mu ọkàn mi jade ninu iṣẹ́.

12. Ati ninu ãnu rẹ ke awọn ọta mi kuro, ki o si run gbogbo awọn ti nni ọkàn mi lara: nitori pe iranṣẹ rẹ li emi iṣe.