Yorùbá Bibeli

Mat 15:23-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ṣugbọn kò si dá a lohùn ọrọ kan. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn bẹ̀ ẹ, wipe, Rán a lọ kuro, nitoriti o nkigbe tọ̀ wá lẹhin.

24. Ṣugbọn o dahùn wipe, A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israeli ti o nù.

25. Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ.

26. Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá.

27. O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ.

28. Nigbana ni Jesu dahùn o si wi fun u pe, Obinrin yi, igbagbọ́ nla ni tirẹ: ki o ri fun ọ gẹgẹ bi iwọ ti nfẹ. A si mu ọmọbinrin rẹ̀ larada ni wakati kanna.

29. Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o wá si eti okun Galili, o gùn ori òke lọ, o si joko nibẹ̀.

30. Ọpọ enia si tọ̀ ọ wá ti awọn ti amukun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ awọn miran, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o si mu wọn larada:

31. Tobẹ̃, ti ẹnu yà ijọ enia na, nigbati nwọn ri ti odi nfọhùn, ti arọ ndi ọ̀tọtọ, ti amukun nrìn, ti afọju si nriran: nwọn si yìn Ọlọrun Israeli logo.

32. Jesu si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọdọ, o si wipe, Anu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn ko si li ohun ti nwọn o jẹ: emi kò si fẹ rán wọn lọ li ebi, ki ãrẹ̀ má bà mu wọn li ọ̀na.

33. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo li awa o ti ri akara to li aginjù, ti yio fi yó ọ̀pọ enia yi?

34. Jesu wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn wipe, Meje, pẹlu ẹja kekeke diẹ.

35. O si paṣẹ ki a mu ijọ enia joko ni ilẹ.

36. O si mu iṣu akara meje, ati ẹja na, o sure, o bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia.

37. Gbogbo nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n meje kún.

38. Awọn ti o jẹun to ẹgbaji ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde.

39. O si rán ijọ enia lọ; o si bọ́ sinu ọkọ̀, o lọ si ẹkùn Magdala.