Yorùbá Bibeli

Luk 9:38-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

38. Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni.

39. Si kiyesi i, ẹmi èṣu a ma mu u, a si ma kigbe lojijì; a si ma nà a tàntàn titi yio fi yọ ifofó li ẹnu, a ma pa a lara, a tilẹ fẹrẹ má fi i silẹ lọ.

40. Mo si bẹ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati lé e jade; nwọn kò si le ṣe e.

41. Jesu si dahùn, wipe, Iran alaigbagbọ́ ati arekereke, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti ṣe sũru fun nyin pẹ to? Fà ọmọ rẹ wá nihinyi.

42. Bi o si ti mbọ̀, ẹmi èṣu na gbé e ṣanlẹ, o si nà a tantan. Jesu si ba ẹmi aimọ́ na wi, o si mu ọmọ na larada, o si fà a le baba rẹ̀ lọwọ.

43. Ẹnu si yà gbogbo wọn si iṣẹ ọlánla Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati hà si nṣe gbogbo wọn si ohun gbogbo ti Jesu ṣe, o wi fun awon ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe,

44. Ẹ jẹ ki ọrọ wọnyi ki o rì si nyin li etí: nitori a o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ.

45. Ṣugbọn ọ̀rọ na ko yé wọn, o si ṣú wọn li oju, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ ọ: ẹ̀ru si mba wọn lati bère idi ọ̀rọ na.