Yorùbá Bibeli

Luk 5:3-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na.

4. Bi o si ti dakẹ ọ̀rọ isọ, o wi fun Simoni pe, Tì si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ̀.

5. Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ.

6. Nigbati nwọn si ti ṣe eyi, nwọn kó ọpọlọpọ ẹja: àwọn wọn si ya.

7. Nwọn si ṣapẹrẹ si ẹgbẹ wọn, ti o wà li ọkọ̀ keji, ki nwọn ki o wá ràn wọn lọwọ. Nwọn si wá, nwọn si kún ọkọ̀ mejeji, bẹ̃ni nwọn bẹ̀rẹ si irì.

8. Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa.

9. Hà si ṣe e, ati gbogbo awọn ti mbẹ pẹlu rẹ̀, fun akopọ̀ ẹja ti nwọn kó:

10. Bẹ̃ ni Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede, ti nṣe olupẹja pọ pẹlu Simoni. Jesu si wi fun Simoni pe, Má bẹ̀ru; lati isisiyi lọ iwọ o ma mú enia.

11. Nigbati nwọn si ti mu ọkọ̀ wọn de ilẹ, nwọn fi gbogbo rẹ̀ silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin lọ.

12. O si ṣe, nigbati o wọ̀ ilu kan, kiyesi i, ọkunrin kan ti ẹ̀tẹ bò: nigbati o ri Jesu, o wolẹ, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́.

13. O si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi kàn a, o ni, Mo fẹ: iwọ di mimọ́. Lọgan ẹ̀tẹ si fi i silẹ lọ.

14. O si kílọ fun u pe, ki o máṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o si fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ́ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹrí si wọn.

15. Ṣugbọn si iwaju li okikí rẹ̀ nkàn kalẹ: ọ̀pọ ijọ enia si jumọ pade lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara lọdọ rẹ̀ kuro lọwọ ailera wọn.

16. O si yẹra si ijù, o si gbadura.

17. O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada.

18. Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀.

19. Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu.