Yorùbá Bibeli

Luk 18:8-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?

9. O si pa owe yi fun awọn kan ti nwọn gbẹkẹle ara wọn pe, awọn li olododo, ti nwọn si ngàn awọn ẹlomiran:

10. Pe, Awọn ọkunrin meji goke lọ si tẹmpili lati gbadura; ọkan jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowode.

11. Eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara rẹ̀ bayi pe, Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi.

12. Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni.

13. Ṣugbọn agbowode duro li òkere, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ̀ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.

14. Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ̀ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, on li a o rẹ̀ silẹ; ẹniti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ on li a o gbéga.

15. Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá pẹlu, ki o le fi ọwọ́ le wọn; ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, nwọn mba wọn wi.

16. Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun.

17. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.

18. Ijoye kan si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi jogún iye ainipẹkun?

19. Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si, bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.

20. Iwọ mọ̀ ofin wọnni, Máṣe ṣe panṣaga, máṣe pania, máṣe jale, máṣe jẹri eke, bọ̀wọ fun baba on iya rẹ.

21. O si wipe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ti pamọ lati igba ewe mi wá.

22. Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin.

23. Nigbati o si gbọ́ eyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi: nitoriti o li ọrọ̀ pipo.

24. Nigbati Jesu ri i pe, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi, o ni, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun!

25. Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.