Yorùbá Bibeli

Luk 13:16-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá?

17. Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá.

18. O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé?

19. O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀.

20. O si tún wipe, Kili emi iba fi ijọba Ọlọrun wé?

21. O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu.

22. O si nlà arin ilu ati iletò lọ, o nkọ́ni, o si nrìn lọ si iha Jerusalemu.

23. Ẹnikan si bi i pe, Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà? O si wi fun wọn pe,

24. Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle.

25. Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá:

26. Nigbana li ẹnyin o bẹ̀rẹ si iwipe, Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọ́ni ni igboro ilu wa.

27. On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ.

28. Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode.

29. Nwọn o si ti ìla-õrùn, ati ìwọ-õrùn wá, ati lati ariwa, ati gusù wá, nwọn o si joko ni ijọba Ọlọrun.