26. Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gbà mi gbọ́, kì yio kú lailai. Iwọ gbà eyi gbọ́?
27. O wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa: emi gbagbọ́ pe, iwọ ni Kristi na Ọmọ Ọlọrun, ẹniti mbọ̀ wá aiye.
28. Nigbati o si ti wi eyi tan, o lọ, o si pè Maria arabinrin rẹ̀ sẹhin wipe, Olukọni de, o si npè ọ.
29. Nigbati o gbọ́, o dide lọgan, o si wá sọdọ rẹ̀.
30. Jesu kò sá ti iwọ̀ ilu, ṣugbọn o wà nibikanna ti Marta pade rẹ̀.
31. Nitorina awọn Ju ti o wà lọdọ rẹ̀ ninu ile, ti nwọn ntù u ninu, nigbati nwọn ri ti Maria dide kánkan, ti o si jade, nwọn tẹ̀le e, nwọn ṣebi o nlọ si ibojì lọ isọkun nibẹ̀.
32. Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú.
33. Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ,
34. O si wipe, Nibo li ẹnyin gbé tẹ́ ẹ si? Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, wá wò o.
35. Jesu sọkun.
36. Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to!
37. Awọn kan ninu wọn si wipe, Ọkunrin yi, ẹniti o là oju afọju, kò le ṣe ki ọkunrin yi má ku bi?
38. Nigbana ni Jesu tún kerora ninu ara rẹ̀, o wá si ibojì. O si jẹ ihò, a si gbé okuta le ẹnu rẹ̀.
39. Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú.