Yorùbá Bibeli

Joṣ 9:23-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Njẹ nitorina ẹnyin di ẹni egún, ẹrú li ẹnyin o si ma jẹ́ titi, ati aṣẹ́gi ati apọnmi fun ile Ọlọrun mi.

24. Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi.

25. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, li ọwọ́ rẹ li awa wà: bi o ti dara si ati bi o ti tọ́ si li oju rẹ lati ṣe wa, ni ki iwọ ki o ṣe.

26. Bẹ̃li o si ṣe wọn, o si gbà wọn li ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si pa wọn.

27. Joṣua si ṣe wọn li aṣẹ́gi ati apọnmi fun ijọ, ati fun pẹpẹ OLUWA li ọjọ́ na, ani titi di oni-oloni, ni ibi ti o ba yàn.