20. Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa.
21. Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai.
22. Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn.
23. Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua.
24. O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.