Yorùbá Bibeli

Joṣ 24:25-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Bẹ̃ni Joṣua bá awọn enia na dá majẹmu li ọjọ́ na, o si fi ofin ati ìlana fun wọn ni Ṣekemu.

26. Joṣua si kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwé ofin Ọlọrun, o si mú okuta nla kan, o si gbé e kà ibẹ̀ labẹ igi-oaku kan, ti o wà ni ibi-mimọ́ OLUWA.

27. Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin.

28. Bẹ̃ni Joṣua jọwọ awọn enia na lọwọ lọ, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀.

29. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún.

30. Nwọn si sin i ni àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnatisera, ti mbẹ ni ilẹ òke Efraimu, ni ìha ariwa òke Gaaṣi.