Yorùbá Bibeli

Joṣ 24:16-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa;

17. Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja:

18. OLUWA si lé gbogbo awọn enia na jade kuro niwaju wa, ani awọn Amori ti ngbé ilẹ na: nitorina li awa pẹlu o ṣe ma sìn OLUWA; nitori on li Ọlọrun wa.

19. Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Enyin kò le sìn OLUWA; nitoripe Ọlọrun mimọ́ li on; Ọlọrun owú li on; ki yio dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.

20. Bi ẹnyin ba kọ̀ OLUWA silẹ, ti ẹ ba si sìn ọlọrun ajeji, nigbana ni on o pada yio si ṣe nyin ni ibi, yio si run nyin, lẹhin ti o ti ṣe nyin li ore tán.

21. Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, Rárá o; ṣugbọn OLUWA li awa o sìn.

22. Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Ẹnyin li ẹlẹri si ara nyin pe, ẹnyin yàn OLUWA fun ara nyin, lati ma sìn i. Nwọn si wipe, Awa ṣe ẹlẹri.

23. Njẹ nitorina ẹ mu ọlọrun ajeji ti mbẹ lãrin nyin kuro, ki ẹnyin si yi ọkàn nyin si OLUWA Ọlọrun Israeli.

24. Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, OLUWA Ọlọrun wa li awa o ma sìn, ohùn rẹ̀ li awa o si ma gbọ́.

25. Bẹ̃ni Joṣua bá awọn enia na dá majẹmu li ọjọ́ na, o si fi ofin ati ìlana fun wọn ni Ṣekemu.

26. Joṣua si kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwé ofin Ọlọrun, o si mú okuta nla kan, o si gbé e kà ibẹ̀ labẹ igi-oaku kan, ti o wà ni ibi-mimọ́ OLUWA.

27. Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin.

28. Bẹ̃ni Joṣua jọwọ awọn enia na lọwọ lọ, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀.