Yorùbá Bibeli

Joṣ 21:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni awọn olori awọn baba awọn ọmọ Lefi sunmọ Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli;

2. Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa.

3. Awọn ọmọ Israeli si fi ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn fun awọn ọmọ Lefi ninu ilẹ-iní wọn, nipa aṣẹ OLUWA.

4. Ipín si yọ fun idile awọn ọmọ Kohati: ati awọn ọmọ Aaroni alufa, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu ẹ̀ya Juda, ati lati inu ẹ̀ya Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya Benjamini.

5. Awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Kohati, fi keké gbà ilu mẹwa lati inu idile ẹ̀ya Efraimu, ati lati inu ẹ̀ya Dani, ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse.

6. Awọn ọmọ Gerṣoni si fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu idile ẹ̀ya Issakari, ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati inu àbọ ẹ̀ya Manasse ni Baṣani.

7. Awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn, ní ilu mejila, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni.

8. Awọn ọmọ Israeli fi keké fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá.

9. Nwọn si fi ilu ti a darukọ wọnyi fun wọn, lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni wá:

10. Nwọn si jẹ́ ti awọn ọmọ Aaroni, ni idile awọn ọmọ Kohati, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, nitoriti nwọn ní ipín ikini.