Yorùbá Bibeli

Joṣ 18:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.

9. Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo.

10. Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.

11. Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu.

12. Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni.

13. Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ.