Yorùbá Bibeli

Joṣ 12:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:

2. Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni;

3. Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga:

4. Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei,

5. O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni.