Yorùbá Bibeli

Joṣ 11:5-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Gbogbo awọn ọba wọnyi si pejọ pọ̀, nwọn wá nwọn si dó ṣọkan ni ibi omi Meromu, lati fi ijà fun Israeli.

6. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

7. Bẹ̃ni Joṣua, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, yọ si wọn lojijì ni ibi omi Meromu, nwọn si kọlù wọn.

8. OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.

9. Joṣua si ṣe si wọn gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o já patì ẹṣin wọn, o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

10. Joṣua si pada li akokò na, o si kó Hasoru, o si fi idà pa ọba rẹ̀: nitori li atijọ́ rí Hasoru li olori gbogbo ilẹ-ọba wọnni.

11. Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, nwọn run wọn patapata: a kò kù ẹnikan ti nmí silẹ: o si fi iná kun Hasoru.

12. Ati gbogbo ilu awọn ọba wọnni, ati gbogbo ọba wọn, ni Joṣua kó, o si fi oju idà kọlù wọn, o si pa wọn run patapata, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti palaṣẹ.

13. Ṣugbọn awọn ilu ti o duro lori òke wọn, Israeli kò sun ọkan ninu wọn, bikoṣe Hasoru nikan; eyi ni Joṣua fi iná sun.

14. Ati gbogbo ikogun ilu wonyi, ati ohunọ̀sin, ni awọn ọmọ Israeli kó fun ara wọn; ṣugbọn gbogbo awọn ọkunrin ni nwọn fi oju kọlù, titi nwọn fi pa wọn run, nwọn kò kù ẹnikan silẹ ti nmí.

15. Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, bẹ̃ni Mose paṣẹ fun Joṣua: bẹ̃ni Joṣua si ṣe; on kò kù ohun kan silẹ ninu gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ fun Mose.

16. Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, ilẹ òke, ati gbogbo ilẹ Gusù, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ati ilẹ titẹju, ati pẹtẹlẹ̀, ati ilẹ òke Israeli, ati ilẹ titẹju rẹ̀;

17. Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.

18. Joṣua si bá gbogbo awọn ọba wọnni jagun li ọjọ́ pipọ̀.