Yorùbá Bibeli

2. Sam 7:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. On o si kọ ile fun orukọ mi, emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ kalẹ lailai.

14. Emi o ma ṣe baba fun u, on o si ma jẹ ọmọ mi. Bi on ba dẹṣẹ, emi o si fi ọpá enia nà a, ati inà awọn ọmọ enia.

15. Ṣugbọn ãnu mi kì yio yipada kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu kuro niwaju rẹ.

16. A o si fi idile rẹ ati ijọba rẹ mulẹ niwaju rẹ titi lai: a o si fi idi itẹ rẹ mulẹ titi lai.

17. Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani si sọ fun Dafidi.

18. Dafidi ọba si wọle lọ, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun, tali emi, ati ki si ni idile mi, ti iwọ fi mu mi di isisiyi?

19. Nkan kekere li eyi sa jasi li oju rẹ, Oluwa Ọlọrun; iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina. Eyi ha ṣe ìwa enia bi, Oluwa Ọlọrun?

20. Kini Dafidi iba si ma wi si i fun ọ? Iwọ, Oluwa Ọlọrun mọ̀ iranṣẹ rẹ.

21. Nitori ọ̀rọ rẹ, ati gẹgẹ bi ifẹ ọkàn rẹ, ni iwọ ṣe gbogbo nkan nla wọnyi, ki iranṣẹ rẹ ki o le mọ̀.

22. Iwọ si tobi, Oluwa Ọlọrun: kò si si ẹniti o dabi rẹ, kò si si Ọlọrun kan lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa fi eti wa gbọ́.

23. Orilẹ-ède kan wo li o si mbẹ li aiye ti o dabi awọn enia rẹ, ani Israeli, awọn ti Ọlọrun lọ ràpada lati sọ wọn di enia rẹ̀, ati lati sọ wọn li orukọ, ati lati ṣe nkan nla fun nyin, ati nkan iyanu fun ilẹ rẹ, niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada fun ara rẹ lati Egipti wá, ani awọn orilẹ-ède ati awọn oriṣa wọn.

24. Iwọ si fi idi awọn enia rẹ, ani Israeli, kalẹ fun ara rẹ lati sọ wọn di enia rẹ titi lai: iwọ Oluwa si wa di Ọlọrun fun wọn.