Yorùbá Bibeli

2. Sam 6:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI si tun ko gbogbo awọn akọni ọkunrin ni Israeli jọ, nwọn si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.

2. Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu.

3. Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na.

4. Nwọn si mu u lati ile Abinadabu jade wá, ti o wà ni Gibea, pẹlu apoti-ẹri Ọlọrun; Ahio si nrìn niwaju apoti-ẹri na.

5. Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro.

6. Nigbati nwọn si de ibi ipakà Nakoni, Ussa si nà ọwọ́ rẹ̀ si apoti-ẹri Ọlọrun, o si dì i mu, nitoriti malu kọsẹ.

7. Ibinu Oluwa si ru si Ussa; Ọlọrun si pa a nibẹ nitori iṣiṣe rẹ̀; nibẹ li o si kú li ẹba apoti-ẹri Ọlọrun.

8. Inu Dafidi si bajẹ nitoriti Oluwa ke Ussa kuro: o si pe orukọ ibẹ na ni Peresi-Ussa titi o fi di oni yi.

9. Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá?

10. Dafidi kò si fẹ mu apoti-ẹri Oluwa sọdọ rẹ̀ si ilu Dafidi: ṣugbọn Dafidi si mu u yà si ile Obedi-Edomu ara Gati.

11. Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀.

12. A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀.

13. O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ.

14. Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.

15. Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.