Yorùbá Bibeli

2. Sam 5:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.

3. Gbogbo agba Israeli si tọ ọba wá ni Hebroni, Dafidi ọba si ba wọn ṣe adehun kan ni Hebroni, niwaju Oluwa: nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba Israeli.

4. Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun.

5. O jọba ni Hebroni li ọdun meje on oṣu mẹfa lori Juda: o si jọba ni Jerusalemu li ọdun mẹtalelọgbọn lori gbogbo Israeli ati Juda.

6. Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin.

7. Ṣugbọn Dafidi si fi agbara gbà ilu odi Sioni: eyi na ni iṣe ilu Dafidi.

8. Dafidi si sọ lọjọ na pe, Ẹnikẹni ti yio kọlu awọn ara Jebusi, jẹ ki o gbà oju àgbàrá, ki o si kọlu awọn arọ ati awọn afọju ti ọkàn Dafidi korira. Nitorina ni nwọn ṣe wipe, Afọju ati arọ wà nibẹ, kì yio le wọle.

9. Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀.

10. Dafidi si npọ̀ si i, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun si wà pẹlu rẹ̀.

11. Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi.

12. Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.