Yorùbá Bibeli

2. Sam 5:12-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.

13. Dafidi si tun mu awọn alè ati aya si i lati Jerusalemu wá, lẹhin igbati o ti Hebroni bọ̀: nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin fun Dafidi.

14. Eyi si ni orukọ awọn ti a bi fun u ni Jerusalemu, Ṣammua ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni,

15. Ati Ibehari, ati Eliṣua, ati Nefegi, ati Jafia,

16. Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifaleti,

17. Ṣugbọn nigbati awọn Filistini gbọ́ pe, nwọn ti fi Dafidi jọba lori Israeli, gbogbo awọn Filistini si goke wá lati wa Dafidi; Dafidi si gbọ́, o si sọkalẹ lọ si ilu odi.

18. Awọn Filistini si wá, nwọn si tẹ́ ara wọn li afonifoji Refaimu.

19. Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ.

20. Dafidi si de Baal-perasimu, Dafidi si pa wọn nibẹ, o si wipe, Oluwa ti ya lù awọn ọtá mi niwaju mi, gẹgẹ bi omi iti ya. Nitorina li on ṣe pe orukọ ibẹ na ni Baal-perasimu.

21. Nwọn si fi oriṣa wọn silẹ nibẹ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si ko wọn.

22. Awọn Filistini si tún goke wá, nwọn si tàn ara wọn kalẹ ni afonifoji Refaimu.

23. Dafidi si bere lọdọ Oluwa, on si wipe, Máṣe goke lọ; ṣugbọn bù wọn lẹhin, ki o si kọlu wọn niwaju awọn igi Baka.